You are here: HomeHis Royal MajestyOriki

ORIKI

Alamu erin

Omo Oloofuja

Omo Akitiolu

Omo erin to gboku nyin ibon ode

Omo o’nta

Omo gbogbondu

Omo Aromire akeru wasa

Omo akenigbo keru ba ara ona

 

Omo belu ojilokiti

Omo awonoku komo oju Oniru

Omo ede l’okun, egbe l’okun omo Akiogun Oniru

Alabat omo owori bikale, adajo n’owo

Adajo ba owo je, Ayenmerenoro

 

Oniru Oba Imahin

Omo olokun, Omo olosa

Omo ede l’okun egbe l’okun

Omo Akiogun Oniru

Omo akenigbo k’eru ba ara ona

Omo asehun ma pekan

Omo apekan ma f’obinrin je

Omo o b’obirin sun, dupe ore ana

N moru iwa, n mose iwa

Omo epo werewere ni Idunganran

Ko se fi oko tu, Ko se f’ada ro

B’a ro a o lo

Omo t’olu ajo, Omo ajidagba bi ogede

Ogede d’agba tan, ara nta won

Eni mi kukute, ara re ni o n mi

Eni fi suru se esu, ara won ni won nse

Omo iroko ilado

Omo ajede ni wasa

Eleyinju agbe seye

baba mi ko obi fun olobi

o ko obi fun osika

oni ki osika fi enu re pa ara re

Omo Kutere asalogun

Omo Esinlokun Erunbi

Omo Akinsemoyin Ado

Iyekan idejo merindinl’ogun l’ogba Olofin